Skip to content
BibleKenya

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Saamu 108

Orin. Saamu ti Dafidi.

Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin

èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin.

Jí ohun èlò orin àti haapu!

Èmi ó jí ní kùtùkùtù,

èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè,

èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn.

Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ

ju àwọn ọ̀run lọ

àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀.

Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run,

àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé.

Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là;

fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà,

kí o sì dá mi lóhùn

Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé,

“Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu,

èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò.

Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi,

Efraimu ni ìbòrí mi,

Juda ni olófin mi,

Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,

lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí,

lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi?

Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?

Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀.

Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́.

Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú,

nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni.

Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin

nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.

Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.

BibleKenya

Reader settings

Theme
Font
Alignment
Reading width

Saved in this browser and used offline too. Press ? for keyboard shortcuts.