Skip to content
BibleKenya

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Saamu 107

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;

nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí,

àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,

àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,

láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,

láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,

wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí

wọn ó máa gbé.

Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,

ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.

Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè

sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn

Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú

tí wọn lè máa gbé.

Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́

ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,

nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run

ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.

Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,

a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,

nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀

Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,

Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;

wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí

yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ní ìgbà náà wọ́n ké pe

Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn

Ó mú wọn jáde kúrò nínú

òkùnkùn àti òjìji ikú,

ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.

Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.

Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì

ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.

Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn

wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ

wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.

Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn,

ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.

Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá

ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.

Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́

kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.

Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi,

wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.

Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.

Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́

tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.

Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì

tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:

nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.

Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:

ọgbọ́n wọn sì dé òpin.

Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè

sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,

ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.

Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́

bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.

Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,

ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.

Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún

Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀

àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.

Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn

kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.

Ó sọ odò di aginjù,

àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀

nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.

O sọ aginjù di adágún omi àti

ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,

níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,

wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.

Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà

tí yóò máa so èso tí ó dára;

Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye

kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.

Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,

ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,

ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé

ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.

Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira

ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.

Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn

ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí

kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.

Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.

BibleKenya

Reader settings

Theme
Font
Alignment
Reading width

Saved in this browser and used offline too. Press ? for keyboard shortcuts.