Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Saamu 21
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
kì yóò sípò padà.
Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.
Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.