Skip to content
BibleKenya

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Saamu 132

Orin fún ìgòkè.

Olúwa, rántí Dafidi

nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.

Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa,

tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.

Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ,

bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.

Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi,

tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,

títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa,

ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.

Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata:

àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.

Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀:

àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀

Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ:

ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.

Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ:

kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.

Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀,

má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.

Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi,

Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀,

nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.

Bí àwọn ọmọ rẹ̀ yóò bá pa májẹ̀mú mi mọ́

àti ẹ̀rí mi tí èmi yóò kọ́ wọn,

àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò jókòó lórí ìtẹ́ rẹ láéláé.

Nítorí tí Olúwa ti yan Sioni:

ó ti fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀.

Èyí ni ibi ìsinmi mi láéláé:

níhìn-ín ni èmi yóò máa gbé:

nítorí tí mo fẹ́ ẹ.

Èmi yóò bùkún oúnjẹ rẹ̀ púpọ̀púpọ̀:

èmi yóò fi oúnjẹ tẹ́ àwọn tálákà rẹ̀ lọ́rùn.

Èmi yóò sì fi ìgbàlà wọ àwọn àlùfáà rẹ̀:

àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ yóò máa hó fún ayọ̀.

Níbẹ̀ ni èmi yóò gbé mú ìwo Dafidi yọ̀,

èmi ti ṣe ìlànà fìtílà kan fún ẹni òróró mi.

Àwọn ọ̀tá rẹ̀ ni èmi yóò fi ìtìjú wọ̀:

ṣùgbọ́n lára òun tìkára rẹ̀ ni adé yóò máa gbilẹ̀.

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.

Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.

BibleKenya

Reader settings

Theme
Font
Alignment
Reading width

Saved in this browser and used offline too. Press ? for keyboard shortcuts.