Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Òwe 22
Orúkọ rere sàn ju ọrọ̀ lọ
Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ,
àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀:
Olúwa ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀,
ó ṣé ara rẹ̀ mọ́:
ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Olúwa ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
Ègún àti ìdẹ̀kùn ń bẹ ní ọ̀nà aláyídáyidà:
ẹni tí ó bá pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yóò jìnnà sí wọn.
Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀:
nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú,
ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn ẹ̀ṣẹ̀, yóò ká asán:
ọ̀pá ìbínú rẹ̀ yóò kùnà.
Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún;
nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
Lé ẹlẹ́gàn sí ìta, ìjà yóò sì jáde;
nítòótọ́ ìjà àti ẹ̀gàn yóò dẹ́kun.
Ẹni tí ó fẹ́ ìwà funfun ti àyà,
tí ó sì ń sọ̀rọ̀ iyì jáde, ọba yóò ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Ojú Olúwa pa ìmọ̀ mọ́,
ó sì yí ọ̀rọ̀ olùrékọjá pò.
Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!
Yóò pa mí ní ìgboro!”
Ẹnu àwọn àjèjì obìnrin, ihò jíjìn ni;
ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.
Àyà ọmọdé ni ìwà wèrè dì sí;
ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
Ẹni tó ń ni tálákà lára láti ní ọrọ̀,
tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,
yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.
Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n
Dẹtí rẹ sílẹ̀,
kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,
kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.
Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;
nígbà tí a sì pèsè wọn tán ní ètè rẹ.
Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà ní ti Olúwa,
èmi fihàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.
Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradára
sí ọ ní ti ìmọ̀ràn àti ní ti ẹ̀kọ́,
kí ó lè mú ọ mọ ìdájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;
kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́
fún àwọn tí ó rán ọ?
Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà:
bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè,
nítorí Olúwa yóò gbèjà wọn,
yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́;
má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
Kí ìwọ má ba à kọ́ ìwà rẹ̀, ìwọ a sì gba ìkẹ́kùn fún ara rẹ.
Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́,
tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.
Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san,
nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?
Má ṣe yẹ ààlà ilẹ̀ ìgbàanì,
tí àwọn baba rẹ ti pa.
Ìwọ ha rí ènìyàn tí ó ń fi àìṣe ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ rẹ̀?
Òun yóò dúró níwájú àwọn ọba;
òun kì yóò dúró níwájú àwọn ènìyàn lásán.
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.
Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.