Skip to content
BibleKenya

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Isaiah 48

Israẹli olórí kunkun

“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,

ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli

tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda,

ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa

tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli

ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,

ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì

tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli—

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,

ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;

lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.

Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;

àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin;

bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.

Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ

ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;

kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín

tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,

‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;

àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’

Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn.

Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?

“Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ

fún ọ nípa nǹkan tuntun,

àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.

A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́

ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.

Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,

‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’

Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí

láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.

Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;

a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.

Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;

nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,

kí a má ba à ké ọ kúrò.

Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé

kì í ṣe bí i fàdákà;

Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí.

Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.

Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.

Israẹli dòmìnira

“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu

Israẹli ẹni tí mo pè.

Èmi ni ẹni náà;

Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.

Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,

àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;

nígbà tí mo pè wọ́n,

gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.

“Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́.

Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.

Olúwa ti fẹ́ ẹ,

yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,

apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.

Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;

bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.

Èmi yóò mú un wá,

òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.

“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:

“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;

ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”

Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,

pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.

Èyí ni ohun tí Olúwa wí,

Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:

“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,

tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,

tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.

Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,

àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,

àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.

Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,

àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;

orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò

tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”

Fi Babeli sílẹ̀,

sá fún àwọn ará Babeli,

ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀

kí o sì kéde rẹ̀.

Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;

wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”

Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn

kọjá nínú aginjù;

ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;

ó fọ́ àpáta

omi sì tú jáde.

“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,

“Fún àwọn ìkà.”

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní. Copyright © 2009, 2017 Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Source: eBible.org. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.

Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-10-25.

BibleKenya

Reader settings

Theme
Font
Alignment
Reading width

Saved in this browser and used offline too. Press ? for keyboard shortcuts.