Skip to content
BibleKenya

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017

Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:

Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.

Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:

yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀

kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.

Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀

yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;

wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.

Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,

“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”

Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,

wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;

nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;

èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,

wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin

àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,

kì yóò dìde mọ́.” 1

Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,

ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,

tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;

gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.

Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,

nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

Bí ó ṣe tèmi ni

ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi

ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli,

láé àti láéláé.

Àmín àti Àmín.

Source notes (1)
  1. Cross-reference Jh 13.18.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible 2017. Copyright © Biblica, Inc. Licensed under CC BY-SA 4.0. Source: Open.Bible. Typeset from the source files; no intended changes to scripture wording. BibleKenya is not endorsed by the rights holder.

Full source notice & licence · CC BY-SA 4.0 · SourceEdition imported 2026-11-09.

BibleKenya

Reader settings

Theme
Font
Alignment
Reading width

Saved in this browser and used offline too. Press ? for keyboard shortcuts.